Deuteronomy 16:9-12

Ayẹyẹ àwọn ọ̀sẹ̀

9Ka ọ̀sẹ̀ méje láti ìgbà tí ẹ bá ti bẹ̀rẹ̀ sí fi dòjé ṣe ìkórè ọkà. 10Nígbà náà ni kí ẹ ṣe àjọ ọ̀sẹ̀ sí Olúwa Ọlọ́run yín, nípa pípèsè ọrẹ àtinúwá, gẹ́gẹ́ bí ìbùkún tí Olúwa Ọlọ́run yín fún un yín. 11Kí ẹ sì máa yọ̀ níwájú Olúwa Ọlọ́run yín ní ibi tí yóò yàn ní ibùgbé fún orúkọ rẹ̀: ẹ̀yin, àwọn ọmọ yín ọkùnrin àti àwọn ọmọ yín obìnrin, àwọn ẹrú yín ọkùnrin àti àwọn ẹrú yín obìnrin, àwọn Lefi tí ó wà ní ìlú yín, àti àwọn àjèjì, àwọn aláìní baba, àti àwọn opó tí ń gbé àárín yín. 12Ẹ rántí pé, ẹ ti jẹ́ ẹrú ní Ejibiti rí, nítorí náà ẹ tẹ̀lé àwọn ìlànà wọ̀nyí dáradára.

Copyright information for YorBMYO